Grandma Said Lyrics by ATS

SHARE

ATS Lyrics

Lyrics of Grandma Said by ATS center on a grandmother’s heartfelt blessings, prayers, and words of wisdom for a loved one. The message emphasizes long life, peace, prosperity, and staying connected to family and faith.

ATANDA SOUNDS Album Cover Art

ATS - Grandma Lyrics

Sálamu Aláyíkùn ooo
Ọkọ′ mi Àtàndá, ẹ kú ọjọ' mẹ′ta ooo
Ẹ'ẹ' ní dámù; Ọlọ́hun ò gbéyìn ga o
Ẹ̀mí gígùn, àlàáfíà Ọlọ́hun ò fì tayin lọ′rẹ o
Ṣẹ′kẹ'rẹ′ owó Ọlọ́hun ò dà léyìn lọ́wọ́ o
Ẹ'ẹ′ ní gbé ìyàwó oníyàwó; ìyàwó tiyín lẹ ó gbé o

Ìyàwó àlùbáríkà
Lọ́lá Ànọ́bì Muhammad
(sallallahu alayhi wa sallam)
Ẹ'ẹ′ ti yé wá bẹ'rẹ' wá, ẹ′hẹ′n?
Ó tó ọjọ́ mẹ'ta
Mo ṣáà n jàran é, jàran é, jàran é, jàran é títí ni!
Bí Ọlọ́hun ṣe wá ni, èmi àti mámà yín àti àbúrò rẹ
A jọ pàdé níbí lónìí

Ó wá dùn mọ′ mi púpọ'
Bí mo tiyẹ′ ṣe gbọ́ ohùn rẹ yìí
Wàláhì, ó dùn mọ' mi, ó dùn mọ′ mi púpọ'!
Ẹ̀mí rẹ ó wá gùn lógo Ọlọ́hun
O ò ní ríkú tó yàwó
O ò ní pa ara mọ' ayé lára
Ẹ̀mí gígùn, àlàáfíà, ìgbélé ayé gbádùn ìròrùn
Ọlọ́hun ó jọgun e fún ọ
Ẹ kú iṣẹ′ ooo!

Ẹ kú iṣẹ′, àmọ' ìwọ náà máa rántí mi oo
Kóo dígbà tá a bá kú tán kè tó máa wá fi kúrisì rántí wa
Máa rántí mi ooo!
Gbogbo ìgbà ni èmi máa ń jàran é
Kódà bí mo ṣe gbúrọ́ rẹ lónìí, ó tún dùn mọ′ mi púpọ'
Ayò mi tún lẹ′kùn
Ìdùnnú mi tún pọ̀ sí!
Kóo wá dá kún, torí Ọlọ́hun, ẹ máa ti gbàgbé wa bá yí
Àìtíkú ayé náà la ṣì wà
Ẹ má ti gbàgbé wa

Ẹ ó rílẹ' rẹ wò lógo Ọlọ́hun
Ìyàwó àlùbáríkà, ọmọ àlùbáríkà Ọlọ́hun ó fì tayin lọ′rẹ
Ẹ'ẹ' ní dámù, ẹ′ẹ′ ní pa ara mọ' ayé lára o
Lọ́lá Ànọ́bì Muhammad, Lọ́lá Ìláfí
Bismillahi Rahmani Rohim
Lí-ííláfí Quráíṣin Íláfíhim ríhlatá sh-shítá-í wa ṣ-ṣóíf
Fál-yá′búdúú rábba háadhál báýt
Al-ladhíi aṭámáhúm min jûúín wa áamanáhúm min khóúf

Àmín mẹ'ta mẹ′ta
Àmíìn, Àmíìn, Àmíìn
Síṣowa ò kú
Ríri wa ò kú
Lágbára Ọlọ́hun
Ọlọ́hun ó sì jẹ' ká ṣì wà lóke yẹ′pẹ'
Lọ́lá Ànọ́bì Muhammad (sallallahu alayhi wa sallam)
Aaní dámù o!

Check Lyrics of latest songs here, and get fresh updates as they drop via X and Facebook

Related